-
Ìṣe 22:27-29Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
27 Ni ọ̀gágun náà bá sún mọ́ Pọ́ọ̀lù, ó ní: “Sọ fún mi, Ṣé ará Róòmù ni ọ́?” Ó sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni.” 28 Ọ̀gágun náà wá sọ pé: “Owó gọbọi ni mo fi ra ẹ̀tọ́ ọmọ ìbílẹ̀ Róòmù.” Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Wọ́n bí èmi síbẹ̀ ni.”+
29 Torí náà, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni àwọn tó fẹ́ fi ìdálóró wádìí ọ̀rọ̀ lẹ́nu rẹ̀ fi í sílẹ̀; ẹ̀rù sì ba ọ̀gágun náà nígbà tí ó mọ̀ pé ará Róòmù ni, torí pé ó ti fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ dè é.+
-