17 Nítorí náà, ohun tí màá sọ, tí màá sì jẹ́rìí sí nínú Olúwa ni pé kí ẹ má ṣe rìn mọ́ bí àwọn orílẹ̀-èdè ṣe ń rìn,+ torí inú èrò asán ni wọ́n ti ń rìn.+ 18 Ìrònú wọn ti ṣókùnkùn, wọ́n sì ti di àjèjì sí ìyè tó jẹ́ ti Ọlọ́run, torí pé wọ́n jẹ́ aláìmọ̀kan àti nítorí ọkàn wọn ti yigbì.