-
Ìṣe 19:9, 10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 Àmọ́ nígbà tí àwọn kan kọ̀ jálẹ̀ pé àwọn ò ní gbà á gbọ́,* tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ burúkú nípa Ọ̀nà Náà+ lójú ọ̀pọ̀ èèyàn, ó kúrò lọ́dọ̀ wọn,+ ó sì ya àwọn ọmọ ẹ̀yìn sọ́tọ̀ kúrò lára wọn, ó ń sọ àsọyé lójoojúmọ́ nínú gbọ̀ngàn àpéjọ ilé ẹ̀kọ́ Tíránù. 10 Èyí ń bá a lọ fún ọdún méjì, tí gbogbo àwọn tó ń gbé ní ìpínlẹ̀ Éṣíà fi gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, àti Júù àti Gíríìkì.
-