3 Nítorí náà, ẹ̀yin ará, ẹ yan àwọn ọkùnrin méje láàárín yín tí wọ́n lórúkọ rere,*+ tí wọ́n kún fún ẹ̀mí àti ọgbọ́n,+ kí a lè yàn wọ́n láti máa bójú tó ọ̀ràn tó pọn dandan yìí;+
5 Ohun tí wọ́n sọ dùn mọ́ gbogbo àwọn èèyàn náà nínú, wọ́n sì yan Sítéfánù, ọkùnrin tó kún fún ìgbàgbọ́ àti ẹ̀mí mímọ́ pẹ̀lú Fílípì,+ Pírókórọ́sì, Níkánọ̀, Tímónì, Páménásì àti Níkóláósì tó jẹ́ aláwọ̀ṣe* ará Áńtíókù.