23 Ó wá pe méjì lára àwọn ọ̀gá ọmọ ogun, ó sì sọ pé: “Ẹ múra igba (200) ọmọ ogun sílẹ̀ láti lọ sí Kesaríà ní wákàtí kẹta òru, ẹ tún mú àádọ́rin (70) agẹṣin àti igba (200) àwọn tó ń fọ̀kọ̀ jà dání. 24 Bákan náà, ẹ fún Pọ́ọ̀lù ní àwọn ẹṣin tó máa gbé e dé ọ̀dọ̀ gómìnà Fẹ́líìsì láìséwu.”