-
Ìṣe 26:22, 23Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
22 Àmọ́ torí pé mo rí ìrànlọ́wọ́ gbà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, mò ń jẹ́rìí nìṣó títí di òní yìí fún ẹni kékeré àti ẹni ńlá, mi ò sì sọ nǹkan kan tó yàtọ̀ sí ohun tí àwọn Wòlíì àti Mósè sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀,+ 23 pé Kristi máa jìyà+ àti pé bó ṣe jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ tí a máa jí dìde kúrò nínú ikú,+ ó máa kéde ìmọ́lẹ̀ fún àwọn èèyàn yìí àti fún àwọn orílẹ̀-èdè.”+
-