38 “Nítorí náà, ẹ̀yin ará, ẹ jẹ́ kó yé yín pé ipasẹ̀ ẹni yìí la fi ń kéde ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ fún yín,+39 àti pé nínú gbogbo ohun tí a kò lè sọ pé ẹ ò jẹ̀bi rẹ̀ nípasẹ̀ Òfin Mósè,+ ni à ń tipasẹ̀ ẹni yìí pe gbogbo ẹni tó bá gbà gbọ́ ní aláìlẹ́bi.+
8 Inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí yìí ti mú kí ẹ rí ìgbàlà nípasẹ̀ ìgbàgbọ́,+ èyí kì í ṣe nípa agbára yín; ẹ̀bùn Ọlọ́run ni. 9 Bẹ́ẹ̀ ni, kì í ṣe nípa iṣẹ́,+ kí ẹnì kankan má bàa ní ìdí láti máa yangàn.