5 Ó wá mú un wá sí ìta, ó sì sọ pé: “Jọ̀ọ́, gbójú sókè wo ọ̀run, kí o sì ka àwọn ìràwọ̀, tí o bá lè kà á.” Ó sì sọ fún un pé: “Bí ọmọ* rẹ á ṣe pọ̀ nìyẹn.”+
17 Nígbà tí a dán Ábúráhámù wò,+ ká kúkú sọ pé ó ti fi Ísákì rúbọ tán torí ìgbàgbọ́—ọkùnrin tó gba àwọn ìlérí náà tayọ̀tayọ̀ fẹ́ fi ọmọkùnrin kan ṣoṣo tó bí rúbọ+— 18 bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ti sọ fún un pé: “Látọ̀dọ̀ Ísákì+ ni ọmọ* rẹ yóò ti wá.”