38 “Nítorí náà, ẹ̀yin ará, ẹ jẹ́ kó yé yín pé ipasẹ̀ ẹni yìí la fi ń kéde ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ fún yín,+39 àti pé nínú gbogbo ohun tí a kò lè sọ pé ẹ ò jẹ̀bi rẹ̀ nípasẹ̀ Òfin Mósè,+ ni à ń tipasẹ̀ ẹni yìí pe gbogbo ẹni tó bá gbà gbọ́ ní aláìlẹ́bi.+
14 ǹjẹ́ ẹ̀jẹ̀ Kristi,+ ẹni tó tipasẹ̀ ẹ̀mí àìnípẹ̀kun fi ara rẹ̀ rúbọ sí Ọlọ́run láìní àbààwọ́n kò ní ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ láti wẹ ẹ̀rí ọkàn wa mọ́ kúrò nínú àwọn òkú iṣẹ́,+ ká lè máa ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún Ọlọ́run alààyè?+