31 Jésù wá sọ fún àwọn Júù tó gbà á gbọ́ pé: “Tí ẹ bá dúró nínú ọ̀rọ̀ mi, ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín lóòótọ́, 32 ẹ ó mọ òtítọ́,+ òtítọ́ á sì sọ yín di òmìnira.”+
25 Àmọ́ ẹni tó bá ń fara balẹ̀ wo inú òfin pípé+ tó jẹ́ ti òmìnira, tí kò sì yéé wò ó, kì í ṣe olùgbọ́ tó ń gbàgbé, àmọ́ ó ti di olùṣe iṣẹ́ náà; ohun tó ń ṣe á sì máa múnú rẹ̀ dùn.+