5 Ní báyìí, kí Ọlọ́run tó ń fúnni ní ìfaradà àti ìtùnú jẹ́ kí ẹ ní èrò kan náà pẹ̀lú Kristi Jésù láàárín ara yín, 6 kí ẹ lè jọ+ máa fi ohùn* kan yin Ọlọ́run àti Baba Olúwa wa Jésù Kristi lógo.
11 Tóò, ẹ̀yin ará, ẹ máa yọ̀, ẹ máa ṣe ìyípadà, ẹ máa gba ìtùnú,+ ẹ máa ronú níṣọ̀kan,+ ẹ máa gbé ní àlàáfíà;+ Ọlọ́run ìfẹ́ àti àlàáfíà+ yóò sì wà pẹ̀lú yín.