-
1 Kọ́ríńtì 6:9, 10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 Àbí ẹ ò mọ̀ pé àwọn aláìṣòdodo kò ní jogún Ìjọba Ọlọ́run ni?+ Ẹ má ṣe jẹ́ kí wọ́n ṣì yín lọ́nà.* Àwọn oníṣekúṣe,*+ àwọn abọ̀rìṣà,+ àwọn alágbèrè,+ àwọn ọkùnrin tó ń jẹ́ kí ọkùnrin bá wọn lò pọ̀,+ àwọn abẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀,*+ 10 àwọn olè, àwọn olójúkòkòrò,+ àwọn ọ̀mùtípara,+ àwọn pẹ̀gànpẹ̀gàn* àti àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà kò ní jogún Ìjọba Ọlọ́run.+
-
-
Gálátíà 5:19-21Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
19 Àwọn iṣẹ́ ti ara hàn kedere, àwọn sì ni ìṣekúṣe,*+ ìwà àìmọ́, ìwà àìnítìjú,*+ 20 ìbọ̀rìṣà, ìbẹ́mìílò,*+ ìkórìíra, wàhálà, owú, inú fùfù, awuyewuye, ìpínyà, ẹ̀ya ìsìn, 21 ìlara, ìmutíyó,+ àwọn àríyá aláriwo àti irú àwọn nǹkan yìí.+ Mò ń kìlọ̀ fún yín ṣáájú nípa àwọn nǹkan yìí, lọ́nà kan náà tí mo gbà kìlọ̀ fún yín tẹ́lẹ̀, pé àwọn tó bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí kò ní jogún Ìjọba Ọlọ́run.+
-