-
Léfítíkù 6:14Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
14 “‘Òfin ọrẹ ọkà+ nìyí: Kí ẹ̀yin ọmọ Áárónì mú un wá síwájú Jèhófà, ní iwájú pẹpẹ.
-
-
Nọ́ńbà 18:30, 31Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
30 “Kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Tí ẹ bá fi èyí tó dáa jù nínú wọn ṣe ọrẹ, yóò jẹ́ ti àwọn ọmọ Léfì bí ohun tó wá láti ibi ìpakà àti ohun tó wá láti ibi tí wọ́n ti ń fún wáìnì tàbí òróró. 31 Ibikíbi ni ẹ̀yin àti agbo ilé yín ti lè jẹ ẹ́, torí èrè iṣẹ́ tí ẹ̀ ń ṣe ní àgọ́ ìpàdé+ ló jẹ́.
-
-
Diutarónómì 18:1Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
18 “Wọn ò ní fún àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Léfì àti gbogbo ẹ̀yà Léfì pátá ní ìpín tàbí ogún kankan ní Ísírẹ́lì. Wọ́n á máa jẹ lára àwọn ọrẹ àfinásun sí Jèhófà, èyí tó jẹ́ tirẹ̀.+
-