3 Bí ó ṣe ń rin ìrìn àjò lọ, tó sì ń sún mọ́ Damásíkù, lójijì, ìmọ́lẹ̀ kan láti ọ̀run kọ mànà yí i ká,+ 4 ó ṣubú lulẹ̀, ó sì gbọ́ tí ohùn kan sọ fún un pé: “Sọ́ọ̀lù, Sọ́ọ̀lù, kí nìdí tí o fi ń ṣe inúnibíni sí mi?” 5 Ó béèrè pé: “Ta ni ọ́, Olúwa?” Ó sọ pé: “Èmi ni Jésù,+ ẹni tí ò ń ṣe inúnibíni sí.+