19 Àmọ́ àwọn Júù dé láti Áńtíókù àti Íkóníónì, wọ́n sì yí àwọn èrò náà lọ́kàn pa dà,+ wọ́n bá sọ Pọ́ọ̀lù lókùúta, wọ́n sì wọ́ ọ sẹ́yìn òde ìlú, wọ́n rò pé ó ti kú.+
8 Wọ́n há wa gádígádí ní gbogbo ọ̀nà, àmọ́ kò le débi tí a ò fi lè yíra; ọkàn wa dà rú, àmọ́ kì í ṣe láìsí ọ̀nà àbáyọ rárá;*+9 wọ́n ṣe inúnibíni sí wa, àmọ́ a ò pa wá tì;+ wọ́n gbé wa ṣánlẹ̀, àmọ́ a ò pa run.+