-
Òwe 28:27Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
27 Ẹni tó bá ń fún aláìní ní nǹkan kò ní ṣaláìní,+
Àmọ́ ẹni tó bá ń gbójú kúrò lára wọn yóò gba ọ̀pọ̀ ègún.
-
-
Fílípì 4:18, 19Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
18 Àmọ́, mo ní ohun gbogbo tí mo nílò, kódà mo ní jù bẹ́ẹ̀ lọ. Mo ti ní ànító, ní báyìí tí àwọn ohun tí ẹ fi rán Ẹpafíródítù+ ti dé ọwọ́ mi, wọ́n dà bí òórùn dídùn,+ ẹbọ tó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tó sì wu Ọlọ́run gidigidi. 19 Nítorí náà, Ọlọ́run mi tí ọrọ̀ rẹ̀ kò lópin máa pèsè gbogbo ohun tí ẹ nílò pátápátá+ nípasẹ̀ Kristi Jésù.
-