18 Tímótì ọmọ mi, mo fi ìtọ́ni yìí sí ìkáwọ́ rẹ, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn nǹkan tí a sọ tẹ́lẹ̀ nípa rẹ, pé kí o lè máa fi wọ́n ja ogun rere,+ 19 kí ìgbàgbọ́ rẹ má ṣe yẹ̀, kí o sì máa ní ẹ̀rí ọkàn rere,+ èyí tí àwọn kan ti sọ nù, tó sì ti mú kí ọkọ̀ ìgbàgbọ́ wọn rì.