18 Nítorí ọ̀pọ̀ èèyàn ló wà, mo sábà máa ń mẹ́nu kàn wọ́n tẹ́lẹ̀, ní báyìí tẹkúntẹkún ni mò ń mẹ́nu kàn wọ́n, àwọn tí wọ́n ń hùwà bí ọ̀tá òpó igi oró Kristi. 19 Ìparun ni ìgbẹ̀yìn wọn, ikùn wọn ni ọlọ́run wọn, ohun ìtìjú ni wọ́n fi ń ṣògo, àwọn nǹkan ti ayé ni wọ́n sì ń rò.+