24 Àmọ́, Sọ́ọ̀lù gbọ́ nípa ohun tí wọ́n ń gbèrò sí òun. Kódà, tọ̀sántòru ni wọ́n ń ṣọ́ àwọn ẹnubodè lójú méjèèjì, kí wọ́n lè pa á. 25 Torí náà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ gbé e, wọ́n sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀ gba ojú ihò kan lára ògiri lóru, wọ́n sọ̀ ọ́ kalẹ̀ nínú apẹ̀rẹ̀.+