-
2 Kọ́ríńtì 12:9, 10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 Àmọ́, ó sọ fún mi pé: “Inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí mi ti tó fún ọ, torí à ń sọ agbára mi di pípé nínú àìlera.”+ Nítorí náà, ṣe ni màá kúkú máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, tí màá sì máa fi àìlera mi yangàn, kí agbára Kristi lè máa wà lórí mi bí àgọ́. 10 Torí náà, mò ń láyọ̀ nínú àìlera, nínú ìwọ̀sí, ní àkókò àìní, nínú inúnibíni àti ìṣòro, nítorí Kristi. Torí nígbà tí mo bá jẹ́ aláìlera, ìgbà náà ni mo di alágbára.+
-