-
1 Kọ́ríńtì 4:11-13Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
11 Títí di wákàtí yìí, ebi ń pa wá,+ òùngbẹ ń gbẹ wá,+ a ò rí aṣọ tó dáa wọ̀,* wọ́n ń nà wá,*+ a ò sì rí ilé gbé, 12 à ń ṣe làálàá, a sì ń fi ọwọ́ ara wa ṣiṣẹ́.+ Nígbà tí wọ́n ń bú wa, à ń súre;+ nígbà tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí wa, à ń fara dà á pẹ̀lú sùúrù;+ 13 nígbà tí wọ́n bà wá lórúkọ jẹ́, a fi ohùn pẹ̀lẹ́ dáhùn;*+ a ti dà bíi pàǹtírí* ayé, èérí ohun gbogbo, títí di báyìí.
-