15 Ọlọ́run wá sọ fún Ábúráhámù pé: “Ní ti Sáráì+ ìyàwó rẹ, má pè é ní Sáráì mọ́, torí Sérà ni yóò máa jẹ́. 16 Èmi yóò bù kún un, màá sì mú kí ó+ bí ọmọkùnrin kan fún ọ; èmi yóò bù kún un, ó máa di àwọn orílẹ̀-èdè; àwọn ọba àwọn èèyàn yóò sì tinú rẹ̀ jáde.”