21 Ní tòótọ́, ẹ̀yin tí ẹ ti di àjèjì àti ọ̀tá nígbà kan rí torí pé àwọn iṣẹ́ burúkú ni èrò yín dá lé, 22 ẹ̀yin ló pa dà mú bá ara rẹ̀ rẹ́ báyìí nípasẹ̀ ẹran ara ẹni tó fi ara rẹ̀ lélẹ̀ fún ikú, kó lè mú yín wá síwájú rẹ̀ ní mímọ́ àti láìní àbààwọ́n àti láìní ẹ̀sùn kankan,+