-
Kólósè 1:25-27Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
25 Mo di òjíṣẹ́ ìjọ yìí nítorí iṣẹ́ ìríjú+ tí Ọlọ́run fún mi nítorí yín láti wàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní kíkún, 26 àṣírí mímọ́+ tí a fi pa mọ́ láti àwọn ètò àwọn nǹkan* tó ti kọjá+ àti láti àwọn ìran tó ti kọjá. Àmọ́ ní báyìí, a ti fi han àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀,+ 27 ìyẹn àwọn tó wu Ọlọ́run pé kí wọ́n mọ ọrọ̀ ológo nípa àṣírí mímọ́ yìí láàárín àwọn orílẹ̀-èdè,+ àṣírí yìí ni Kristi tó wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú yín, ìyẹn ìrètí ògo rẹ̀.+
-