13 bó tiẹ̀ jẹ́ pé asọ̀rọ̀ òdì ni mí tẹ́lẹ̀, mo máa ń ṣe inúnibíni, mo sì jẹ́ aláfojúdi.+ Síbẹ̀, a fi àánú hàn sí mi, torí àìmọ̀kan ni mo fi hùwà, mi ò sì ní ìgbàgbọ́. 14 Àmọ́ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Olúwa wa pọ̀ gan-an, bẹ́ẹ̀ sì ni ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ tó wà nínú Kristi Jésù.