4 “Ní tòótọ́, irú ìgbésí ayé tí mo gbé láti ìgbà èwe mi láàárín àwọn èèyàn mi àti ní Jerúsálẹ́mù ni gbogbo àwọn Júù mọ̀ dáadáa,+ 5 ìyẹn àwọn tó ti mọ̀ mí tipẹ́tipẹ́, tí wọ́n bá fẹ́, wọ́n lè jẹ́rìí sí i pé ìgbé ayé Farisí ni mo gbé+ ní ìlànà ẹ̀ya ìsìn tí kò gba gbẹ̀rẹ́ rárá,+ ti ọ̀nà ìjọsìn wa.