16 nítorí Olúwa fúnra rẹ̀ yóò sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run pẹ̀lú ìpè àṣẹ, pẹ̀lú ohùn olú áńgẹ́lì+ àti pẹ̀lú kàkàkí Ọlọ́run, àwọn tó ti kú nínú Kristi ló sì máa kọ́kọ́ dìde.+
6 Aláyọ̀ àti ẹni mímọ́ ni ẹnikẹ́ni tó nípìn-ín nínú àjíǹde àkọ́kọ́;+ ikú kejì+ kò ní àṣẹ lórí wọn,+ àmọ́ wọ́n máa jẹ́ àlùfáà+ Ọlọ́run àti ti Kristi, wọ́n sì máa jọba pẹ̀lú rẹ̀ fún ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún náà.+