20 nígbà tó lò ó láti gbé Kristi dìde kúrò nínú ikú, tó sì mú un jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀+ ní àwọn ibi ọ̀run, 21 tí ó ga ju gbogbo ìjọba àti àṣẹ àti agbára àti ipò olúwa àti gbogbo orúkọ tí à ń pè,+ kì í ṣe nínú ètò àwọn nǹkan yìí nìkan, àmọ́ nínú èyí tó ń bọ̀ pẹ̀lú.