2 Nígbà náà, tí ìṣírí èyíkéyìí bá wà nínú Kristi, tí ìtùnú onífẹ̀ẹ́ èyíkéyìí bá wà, tí àjọṣe tẹ̀mí èyíkéyìí bá wà, tí ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ àti àánú bá wà, 2 ẹ jẹ́ kí èrò yín àti ìfẹ́ yín ṣọ̀kan kí ẹ lè mú ayọ̀ mi kún, kí ẹ wà níṣọ̀kan délẹ̀délẹ̀, kí ẹ sì ní èrò kan náà lọ́kàn.+