10 kí ẹ lè máa rìn lọ́nà tó yẹ Jèhófà* láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀ ní kíkún, bí ẹ ṣe ń so èso nínú gbogbo iṣẹ́ rere, tí ìmọ̀ tó péye tí ẹ ní nípa Ọlọ́run sì ń pọ̀ sí i;+
12 Ẹ jẹ́ oníwà rere láàárín àwọn orílẹ̀-èdè,+ kó lè jẹ́ pé tí wọ́n bá fẹ̀sùn ìwà ibi kàn yín, wọ́n á lè fojú ara wọn rí àwọn iṣẹ́ àtàtà yín,+ kí wọ́n sì torí ẹ̀ yin Ọlọ́run lógo lọ́jọ́ àbẹ̀wò rẹ̀.