15 Àmọ́ Olúwa sọ fún un pé: “Lọ! nítorí ohun èlò tí a ti yàn ni ọkùnrin yìí jẹ́ fún mi+ láti mú orúkọ mi lọ sọ́dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè+ àti àwọn ọba+ àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.
7 Torí ìjẹ́rìí yìí + ni a ṣe yàn mí láti jẹ́ oníwàásù àti àpọ́sítélì+—òótọ́ ni mò ń sọ, mi ò parọ́—olùkọ́ àwọn orílẹ̀-èdè+ ní ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́ àti òtítọ́.