-
Ìṣe 2:29-32Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
29 “Ẹ̀yin èèyàn, ẹ̀yin ará, ẹ jẹ́ kí n sọ̀rọ̀ ní fàlàlà fún yín nípa Dáfídì, olórí ìdílé, pé ó kú, wọ́n sin ín,+ ibojì rẹ̀ sì wà lọ́dọ̀ wa títí di òní yìí. 30 Nítorí pé wòlíì ni, ó sì mọ̀ pé Ọlọ́run ti búra fún òun pé òun máa gbé ọ̀kan lára àwọn ọmọ rẹ̀* gorí ìtẹ́ rẹ̀,+ 31 ó ti rí i tẹ́lẹ̀, ó sì sọ nípa àjíǹde Kristi, pé a kò fi í sílẹ̀ nínú Isà Òkú,* bẹ́ẹ̀ ni ara rẹ̀ kò rí ìdíbàjẹ́.*+ 32 Ọlọ́run jí Jésù yìí dìde, gbogbo wa sì jẹ́rìí sí i.+
-