-
1 Tímótì 1:3, 4Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 Bí mo ṣe gbà ọ́ níyànjú nígbà tí mo fẹ́ lọ sí Makedóníà pé kí o dúró ní Éfésù, bẹ́ẹ̀ náà ni mò ń ṣe báyìí, kí o lè pàṣẹ fún àwọn kan pé kí wọ́n má ṣe fi ẹ̀kọ́ tó yàtọ̀ kọ́ni, 4 kí wọ́n má sì tẹ́tí sí àwọn ìtàn èké+ àti àwọn ìtàn ìdílé. Irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ kò wúlò rárá,+ ṣe ló ń mú káwọn èèyàn máa méfò dípò kó máa fúnni ní ohunkóhun látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ìyẹn ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú ìgbàgbọ́.
-
-
Títù 3:9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 Ṣùgbọ́n má ṣe bá ẹnikẹ́ni fa ọ̀rọ̀ tí kò mọ́gbọ́n dání àti ọ̀rọ̀ ìtàn ìdílé, má sì dá sí ìjiyàn àti ìjà lórí Òfin, torí wọn kò lérè, wọn kò sì wúlò.+
-