-
1 Tímótì 1:9, 10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 ó yé wa pé torí olódodo kọ́ ni òfin ṣe wà, àmọ́ ó wà torí àwọn arúfin + àtàwọn ọlọ̀tẹ̀, àwọn tí kò ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run àtàwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, àwọn aláìṣòótọ́* àti aláìmọ́, àwọn tó ń pa bàbá àti àwọn tó ń pa ìyá, àwọn apààyàn, 10 àwọn oníṣekúṣe,* àwọn ọkùnrin tó ń bá ọkùnrin lò pọ̀,* àwọn ajínigbé, àwọn òpùrọ́, àwọn tó ń parọ́ nílé ẹjọ́* àti torí gbogbo àwọn nǹkan míì tó ta ko ẹ̀kọ́ tó ṣàǹfààní*+
-