12 Épáfírásì+ tó ti àárín yín wá, ẹrú Kristi Jésù, kí yín. Ìgbà gbogbo ló ń gbàdúrà lójú méjèèjì nítorí yín, pé níkẹyìn, kí ẹ lè dúró ní pípé, kí ẹ sì ní ìdánilójú nínú gbogbo ìfẹ́ Ọlọ́run. 13 Mo jẹ́rìí rẹ̀ pé ó ń sapá gan-an nítorí yín àti nítorí àwọn tó wà ní Laodíkíà àti ní Hirapólísì.