8 Ní báyìí, sọ fún Dáfídì ìránṣẹ́ mi pé, ‘Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí: “Mo mú ọ láti ibi ìjẹko, pé kí o má da agbo ẹran mọ́,+ kí o lè wá di aṣáájú àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì.+
12 Nígbà tí o bá kú,+ tí o sì sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ, nígbà náà, màá gbé ọmọ* rẹ dìde lẹ́yìn rẹ, ọmọ ìwọ fúnra rẹ,* màá sì fìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀.+