ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àwọn Onídàájọ́ 14:5, 6
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 5 Sámúsìn pẹ̀lú bàbá àti ìyá rẹ̀ wá sọ̀ kalẹ̀ lọ sí Tímúnà. Nígbà tó dé àwọn ọgbà àjàrà Tímúnà, wò ó! kìnnìún* kan ń ké ramúramù bọ̀ wá bá a. 6 Àmọ́ ẹ̀mí Jèhófà fún un lágbára,+ ó sì fà á ya sí méjì, bí èèyàn ṣe ń fi ọwọ́ lásán fa ọmọ ewúrẹ́ ya sí méjì. Àmọ́ kò sọ ohun tó ṣe fún bàbá àti ìyá rẹ̀.

  • 1 Sámúẹ́lì 17:34-36
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 34 Ni Dáfídì bá sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: “Nígbà tí ìránṣẹ́ rẹ ń ṣọ́ agbo ẹran bàbá rẹ̀, kìnnìún+ kan wá, lẹ́yìn náà bíárì kan wá pẹ̀lú, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì gbé àgùntàn lọ nínú agbo ẹran. 35 Mo gbá tẹ̀ lé e, mo mú un balẹ̀, mo sì gba àgùntàn náà sílẹ̀ lẹ́nu rẹ̀. Nígbà tó dìde sí mi, mo gbá a mú níbi irun ọrùn rẹ̀,* mo mú un balẹ̀, mo sì pa á. 36 Àti kìnnìún àti bíárì náà ni ìránṣẹ́ rẹ pa, Filísínì aláìdádọ̀dọ́* yìí á sì dà bí ọ̀kan lára wọn, nítorí ó ti pẹ̀gàn àwọn ìlà ogun Ọlọ́run alààyè.”*+

  • Dáníẹ́lì 6:21, 22
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 21 Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Dáníẹ́lì sọ fún ọba pé: “Ìwọ ọba, kí ẹ̀mí rẹ gùn títí láé. 22 Ọlọ́run mi rán áńgẹ́lì rẹ̀, ó sì dí àwọn kìnnìún náà lẹ́nu,+ wọn ò sì ṣe mí léṣe,+ torí ó rí i pé mi ò mọwọ́ mẹsẹ̀; mi ò sì ṣe ohun burúkú kankan sí ìwọ ọba.”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́