11 “Ẹ wá sún mọ́ tòsí òkè náà, ẹ sì dúró sí ìsàlẹ̀ rẹ̀, òkè náà sì ń yọ iná títí dé ọ̀run; òkùnkùn ṣú, ìkùukùu yọ, ojú ọjọ́ sì ṣú dùdù.+ 12 Jèhófà wá bẹ̀rẹ̀ sí í bá yín sọ̀rọ̀ látinú iná náà.+ Ẹ̀ ń gbọ́ tí ẹnì kan ń sọ̀rọ̀, àmọ́ ẹ ò rí ẹnì kankan,+ ohùn nìkan lẹ̀ ń gbọ́.+