12 Ẹ̀yin ará, ẹ ṣọ́ra, kí ẹnì kankan nínú yín má lọ ní ọkàn burúkú tí kò ní ìgbàgbọ́, tí á mú kó fi Ọlọ́run alààyè sílẹ̀;+ 13 àmọ́ ẹ máa fún ara yín níṣìírí lójoojúmọ́, tí a bá ṣì ń pè é ní “Òní,”+ kí agbára ìtannijẹ ẹ̀ṣẹ̀ má bàa sọ ìkankan nínú yín di ọlọ́kàn líle.