ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jòhánù 1:12, 13
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 12 Ṣùgbọ́n ó fún gbogbo àwọn tó gbà á ní àṣẹ láti di ọmọ Ọlọ́run,+ torí pé wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú orúkọ rẹ̀.+ 13 A ò bí wọn látinú ẹ̀jẹ̀ tàbí látinú ìfẹ́ ti ara tàbí látinú ìfẹ́ èèyàn, àmọ́ a bí wọn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run.+

  • Róòmù 8:28
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 28 A mọ̀ pé Ọlọ́run ń mú kí gbogbo ohun tó ń ṣe máa ṣiṣẹ́ pọ̀ fún ire àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, àwọn tí a pè nítorí ìfẹ́ rẹ̀;+

  • Éfésù 1:13, 14
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 13 Àmọ́ ẹ̀yin náà nírètí nínú rẹ̀ lẹ́yìn tí ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ òtítọ́, ìyẹn ìhìn rere nípa ìgbàlà yín. Lẹ́yìn tí ẹ gbà á gbọ́, a fi ẹ̀mí mímọ́ tí a ṣèlérí gbé èdìdì lé yín+ nípasẹ̀ rẹ̀, 14 ẹ̀mí mímọ́ yìí jẹ́ àmì ìdánilójú* ogún tí à ń retí,+ kí àwọn èèyàn* Ọlọ́run lè rí ìtúsílẹ̀+ nípasẹ̀ ìràpadà,+ sí ìyìn àti ògo rẹ̀.

  • 2 Tẹsalóníkà 2:13
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 13 Síbẹ̀, ó di dandan fún wa láti máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nígbà gbogbo nítorí yín, ẹ̀yin ará tí Jèhófà* nífẹ̀ẹ́, torí pé àtìbẹ̀rẹ̀ ni Ọlọ́run ti yàn yín+ fún ìgbàlà nípa fífi ẹ̀mí rẹ̀ sọ yín di mímọ́+ àti nípa ìgbàgbọ́ yín nínú òtítọ́.

  • 1 Pétérù 1:23
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 23 Torí a ti fún yín ní ìbí tuntun,+ kì í ṣe nípasẹ̀ irúgbìn* tó lè bà jẹ́, àmọ́ nípasẹ̀ irúgbìn tí kò lè bà jẹ́,+ nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run alààyè, tó wà títí láé.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́