11 Tóò, ẹ̀yin ará, ẹ máa yọ̀, ẹ máa ṣe ìyípadà, ẹ máa gba ìtùnú,+ ẹ máa ronú níṣọ̀kan,+ ẹ máa gbé ní àlàáfíà;+ Ọlọ́run ìfẹ́ àti àlàáfíà+ yóò sì wà pẹ̀lú yín.
14 Nítorí náà, ẹ̀yin ará mi ọ̀wọ́n, bí ẹ ṣe ń retí àwọn nǹkan yìí, ẹ sa gbogbo ipá yín kó lè bá yín nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín láìní èérí àti àbààwọ́n àti ní àlàáfíà.+