7 Mo ti ja ìjà rere náà,+ mo ti sá eré ìje náà dé ìparí,+ mo ti pa ìgbàgbọ́ mọ́. 8 Láti ìsinsìnyí lọ, a ti fi adé òdodo + pa mọ́ dè mí, èyí tí Olúwa, onídàájọ́ òdodo,+ máa fi san mí lẹ́san ní ọjọ́ yẹn,+ síbẹ̀ kì í ṣe fún èmi nìkan, àmọ́ fún gbogbo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ ìfarahàn rẹ̀.