-
Jẹ́nẹ́sísì 19:15, 16Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
15 Bí ilẹ̀ ṣe ń mọ́, àwọn áńgẹ́lì náà bẹ̀rẹ̀ sí í kán Lọ́ọ̀tì lójú, wọ́n ń sọ pé: “Dìde! Mú ìyàwó rẹ àti àwọn ọmọ rẹ méjèèjì tó wà níbí pẹ̀lú rẹ, kí ẹ má bàa pa run nígbà tí ìlú+ náà bá ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀!” 16 Àmọ́ nígbà tó ń lọ́ra ṣáá, àwọn ọkùnrin náà gbá ọwọ́ rẹ̀ mú àti ọwọ́ ìyàwó rẹ̀ àti ọwọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ méjèèjì, torí Jèhófà yọ́nú sí i,+ wọ́n mú un jáde, wọ́n sì mú un wá sí ìta ìlú náà.+
-