-
Nọ́ńbà 22:31Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
31 Jèhófà wá la Báláámù lójú,+ ó sì rí áńgẹ́lì Jèhófà tó dúró sójú ọ̀nà, tó sì ti fa idà yọ. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó tẹrí ba, ó sì dojú bolẹ̀.
-
-
Nọ́ńbà 22:34Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
34 Báláámù wá sọ fún áńgẹ́lì Jèhófà pé: “Mo ti ṣẹ̀, torí mi ò mọ̀ pé ìwọ lo dúró sójú ọ̀nà láti pàdé mi. Tó bá jẹ́ pé inú rẹ ò dùn sí i, màá pa dà.”
-
-
Nọ́ńbà 31:8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Yàtọ̀ sí àwọn tí wọ́n pa, wọ́n tún pa àwọn ọba Mídíánì, ìyẹn Éfì, Rékémù, Súúrì, Húrì àti Rébà, àwọn ọba Mídíánì márààrún. Wọ́n tún fi idà pa Báláámù+ ọmọ Béórì.
-