-
Júùdù 12, 13Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
12 Àwọn yìí máa ń wà níbi àsè tí ẹ fìfẹ́ pe ara yín sí,+ àmọ́ wọ́n dà bí àpáta tó fara pa mọ́ lábẹ́ omi. Olùṣọ́ àgùntàn tí kò bẹ̀rù Ọlọ́run ni wọ́n, ara wọn nìkan ni wọ́n ń bọ́.+ Wọ́n dà bí ìkùukùu* tí kò lómi tí atẹ́gùn ń gbá síbí sọ́hùn-ún.+ Wọ́n dà bí igi tí kò léso nígbà ìwọ́wé, tó ti kú pátápátá,* tí a ti hú tegbòtegbò; 13 wọ́n dà bí ìgbì òkun líle tí ń ru ìfófòó ìtìjú ara rẹ̀ sókè + àti bí ìràwọ̀ tí kò ní ọ̀nà tó ń tọ̀, tí yóò wà nínú òkùnkùn biribiri títí láé.+
-