16 Ó sọ ọ́ di ọ̀ranyàn fún gbogbo èèyàn—ẹni kékeré àti ẹni ńlá, ọlọ́rọ̀ àti òtòṣì, ẹni tó wà lómìnira àti ẹrú—pé kí wọ́n sàmì sí ọwọ́ ọ̀tún wọn tàbí iwájú orí wọn,+ 17 àti pé kí ẹnì kankan má lè rà tàbí tà àfi ẹni tó bá ní àmì náà, orúkọ+ ẹranko náà tàbí nọ́ńbà orúkọ rẹ̀.+