-
Ìfihàn 13:15-17Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
15 A gbà á láyè pé kó fún ère ẹranko náà ní èémí,* kí ère ẹranko náà lè sọ̀rọ̀, kó sì mú kí wọ́n pa gbogbo àwọn tó kọ̀ láti jọ́sìn ère ẹranko náà.
16 Ó sọ ọ́ di ọ̀ranyàn fún gbogbo èèyàn—ẹni kékeré àti ẹni ńlá, ọlọ́rọ̀ àti òtòṣì, ẹni tó wà lómìnira àti ẹrú—pé kí wọ́n sàmì sí ọwọ́ ọ̀tún wọn tàbí iwájú orí wọn,+ 17 àti pé kí ẹnì kankan má lè rà tàbí tà àfi ẹni tó bá ní àmì náà, orúkọ+ ẹranko náà tàbí nọ́ńbà orúkọ rẹ̀.+
-