Ìsíkíẹ́lì
15 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 2 “Ọmọ èèyàn, ọ̀nà wo ni igi àjàrà gbà jọ àwọn igi yòókù tàbí àwọn ẹ̀ka igi inú igbó? 3 Ǹjẹ́ igi rẹ̀ wúlò fún iṣẹ́ kankan? Àbí àwọn èèyàn lè fi igi rẹ̀ ṣe èèkàn tí wọ́n á máa fi nǹkan kọ́? 4 Wò ó! Wọ́n fi dáná, iná jó o lórí àti ní ìdí, àárín rẹ̀ sì gbẹ. Ṣé ó wá wúlò fún iṣẹ́ kankan báyìí? 5 Nígbà tó ṣì wà lódindi, kò wúlò fún ohunkóhun. Ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ ìgbà tí iná jó o, tó sì gbẹ!”
6 “Torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Bí igi àjàrà láàárín àwọn igi inú igbó, tí mo ti sọ di ohun ìdáná, bẹ́ẹ̀ ni màá ṣe fún àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù.+ 7 Mo ti gbéjà kò wọ́n. Wọ́n bọ́ lọ́wọ́ iná, síbẹ̀ iná máa jó wọn run. Ẹ ó sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà, nígbà tí mo bá gbéjà kò wọ́n.’”+
8 “‘Èmi yóò sì sọ ilẹ̀ náà di ahoro,+ torí pé wọ́n ti hùwà àìṣòótọ́,’+ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.”