Sáàmù
Orin Ìgòkè.
129 “Láti ìgbà èwe mi ni wọ́n ti ń gbógun tì mí”+
—Kí Ísírẹ́lì sọ pé—
2 “Láti ìgbà èwe mi ni wọ́n ti ń gbógun tì mí;+
Àmọ́, wọn kò ṣẹ́gun mi.+
5 Ojú á tì wọ́n, wọ́n á sì sá pa dà nínú ìtìjú,
Gbogbo àwọn tó kórìíra Síónì.+
6 Wọ́n á dà bíi koríko orí òrùlé
Tó ti rọ kí a tó fà á tu,
7 Tí kò lè kún ọwọ́ ẹni tó ń kórè,
Tàbí apá ẹni tó ń kó ìtí jọ.
8 Àwọn tó ń kọjá lọ kò ní sọ pé:
“Kí ìbùkún Jèhófà wà lórí yín;
A súre fún yín ní orúkọ Jèhófà.”