ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ìsíkíẹ́lì 12
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ìsíkíẹ́lì

      • Ó fi àwọn àmì sọ tẹ́lẹ̀ pé wọ́n á lọ sígbèkùn (1-20)

        • Ẹrù ìgbèkùn (1-7)

        • Ìjòyè yóò lọ nínú òkùnkùn (8-16)

        • Wọ́n jẹ búrẹ́dì láìní ìfọ̀kànbalẹ̀, wọ́n mu omi pẹ̀lú ìbẹ̀rù (17-20)

      • Ọlọ́run sọ pé irọ́ ni ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn wọn (21-28)

        • “Kò sí èyí tó máa falẹ̀ nínú gbogbo ọ̀rọ̀ mi” (28)

Ìsíkíẹ́lì 12:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 6:9, 10; Jer 5:21; Ro 11:8
  • +Isk 2:3, 5

Ìsíkíẹ́lì 12:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 36:20; Jer 52:10, 11

Ìsíkíẹ́lì 12:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 25:4

Ìsíkíẹ́lì 12:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 8:18; Isk 4:3; 24:24

Ìsíkíẹ́lì 12:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 21:7; Isk 21:25

Ìsíkíẹ́lì 12:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 24:24
  • +Jer 52:15

Ìsíkíẹ́lì 12:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 25:4; Jer 39:4

Ìsíkíẹ́lì 12:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 52:9; Isk 17:20, 21
  • +2Ọb 25:6, 7; Jer 34:3; 52:11; Isk 17:16

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 5/2017,

Ìsíkíẹ́lì 12:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 25:5
  • +Le 26:33; Jer 42:15, 16

Ìsíkíẹ́lì 12:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 26:26

Ìsíkíẹ́lì 12:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 6:11; Sek 7:14
  • +Sm 107:33, 34; Jer 6:7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 53

Ìsíkíẹ́lì 12:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 64:10; Jer 25:9
  • +Isk 6:13

Ìsíkíẹ́lì 12:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 5:19; Emọ 6:3; 2Pe 3:3, 4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 53

Ìsíkíẹ́lì 12:23

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joẹ 2:1; Sef 1:14

Ìsíkíẹ́lì 12:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 14:14; Ida 2:14; Isk 13:23

Ìsíkíẹ́lì 12:25

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ida 2:17; Sek 1:6
  • +Jer 16:9; Hab 1:5

Ìsíkíẹ́lì 12:27

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ilé.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 5:19; 28:15; 2Pe 3:3, 4

Àwọn míì

Ìsík. 12:2Ais 6:9, 10; Jer 5:21; Ro 11:8
Ìsík. 12:2Isk 2:3, 5
Ìsík. 12:42Kr 36:20; Jer 52:10, 11
Ìsík. 12:52Ọb 25:4
Ìsík. 12:6Ais 8:18; Isk 4:3; 24:24
Ìsík. 12:10Jer 21:7; Isk 21:25
Ìsík. 12:11Isk 24:24
Ìsík. 12:11Jer 52:15
Ìsík. 12:122Ọb 25:4; Jer 39:4
Ìsík. 12:13Jer 52:9; Isk 17:20, 21
Ìsík. 12:132Ọb 25:6, 7; Jer 34:3; 52:11; Isk 17:16
Ìsík. 12:142Ọb 25:5
Ìsík. 12:14Le 26:33; Jer 42:15, 16
Ìsík. 12:18Le 26:26
Ìsík. 12:19Ais 6:11; Sek 7:14
Ìsík. 12:19Sm 107:33, 34; Jer 6:7
Ìsík. 12:20Ais 64:10; Jer 25:9
Ìsík. 12:20Isk 6:13
Ìsík. 12:22Ais 5:19; Emọ 6:3; 2Pe 3:3, 4
Ìsík. 12:23Joẹ 2:1; Sef 1:14
Ìsík. 12:24Jer 14:14; Ida 2:14; Isk 13:23
Ìsík. 12:25Ida 2:17; Sek 1:6
Ìsík. 12:25Jer 16:9; Hab 1:5
Ìsík. 12:27Ais 5:19; 28:15; 2Pe 3:3, 4
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Ìsíkíẹ́lì 12:1-28

Ìsíkíẹ́lì

12 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 2 “Ọmọ èèyàn, àárín ọlọ̀tẹ̀ ilé lò ń gbé. Wọ́n ní ojú láti rí, àmọ́ wọn ò ríran, wọ́n ní etí láti gbọ́, àmọ́ wọn ò gbọ́ràn,+ torí ọlọ̀tẹ̀ ilé ni wọ́n.+ 3 Ní tìrẹ, ọmọ èèyàn, di ẹrù tí wàá gbé lọ sí ìgbèkùn. Kí o wá lọ sí ìgbèkùn ní ojúmọmọ níṣojú wọn. Lọ sí ìgbèkùn láti ilé rẹ sí ibòmíì níṣojú wọn. Bóyá wọ́n á kíyè sí i, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọlọ̀tẹ̀ ilé ni wọ́n. 4 Gbé ẹrù tí o fẹ́ kó lọ sí ìgbèkùn jáde ní ojúmọmọ níṣojú wọn, tó bá sì di ìrọ̀lẹ́, kí o kúrò nílé níṣojú wọn bí ẹni tí wọ́n ń mú lọ sí ìgbèkùn.+

5 “Dá ògiri lu níṣojú wọn, kí o sì gbé ẹrù rẹ gba inú ihò náà.+ 6 Gbé ẹrù rẹ lé èjìká níṣojú wọn, kí o sì gbé e jáde nínú òkùnkùn. Bo ojú rẹ kí o má bàa rí ilẹ̀, torí èmi yóò fi ọ́ ṣe àmì fún ilé Ísírẹ́lì.”+

7 Mo ṣe ohun tó pa láṣẹ fún mi. Ní ojúmọmọ, mo gbé ẹrù mi jáde bí ẹrù ẹni tó ń lọ sí ìgbèkùn, mo sì fi ọwọ́ dá ògiri náà lu ní ìrọ̀lẹ́. Nígbà tí ilẹ̀ sì ṣú, ìṣojú wọn gan-an ni mo ṣe gbé ẹrù mi jáde lórí èjìká mi.

8 Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 9 “Ọmọ èèyàn, ṣebí ilé Ísírẹ́lì tí wọ́n jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ ilé bi ọ́ pé, ‘Kí lò ń ṣe?’ 10 Sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Ọ̀rọ̀ yìí kan ìjòyè+ Jerúsálẹ́mù àti gbogbo ilé Ísírẹ́lì tó wà nínú ìlú náà.”’

11 “Sọ pé, ‘Àmì ni mo jẹ́ fún yín.+ Ohun tí mo ṣe ni wọ́n á ṣe sí wọn. Wọn yóò lọ sí ìgbèkùn, wọ́n á kó wọn lẹ́rú.+ 12 Ìjòyè àárín wọn yóò gbé ẹrù rẹ̀ lé èjìká, yóò sì lọ nínú òkùnkùn. Ó máa dá ògiri lu, yóò sì gbé ẹrù rẹ̀ gba inú ihò náà.+ Ó máa bo ojú rẹ̀ kó má bàa rí ilẹ̀.’ 13 Èmi yóò ju àwọ̀n mi sí i láti fi mú un.+ Màá wá mú un lọ sí Bábílónì, sí ilẹ̀ àwọn ará Kálídíà, àmọ́ kò ní rí i; ibẹ̀ ló sì máa kú sí.+ 14 Gbogbo àwọn tó yí i ká, àwọn olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ni màá fọ́n káàkiri;+ èmi yóò sì fa idà yọ kí n lè lé wọn bá.+ 15 Wọ́n á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà nígbà tí mo bá fọ́n wọn káàkiri àwọn orílẹ̀-èdè, tí mo sì tú wọn ká sí àwọn ilẹ̀ náà. 16 Àmọ́ màá gba díẹ̀ lára wọn lọ́wọ́ idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀ àrùn, kí wọ́n lè ròyìn gbogbo ohun tó ń ríni lára tí wọ́n ṣe láàárín àwọn orílẹ̀-èdè tí wọn yóò lọ; wọ́n á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.”

17 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 18 “Ọmọ èèyàn, máa gbọ̀n rìrì bí o ṣe ń jẹ oúnjẹ rẹ, kí ẹ̀rù máa bà ọ́, kí ọkàn rẹ má sì balẹ̀ bí o ṣe ń mu omi rẹ.+ 19 Sọ fún àwọn èèyàn ilẹ̀ náà pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ fún àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì nìyí: “Ọkàn wọn ò ní balẹ̀ bí wọ́n ṣe ń jẹ oúnjẹ wọn, ẹ̀rù á sì máa bà wọ́n bí wọ́n ṣe ń mu omi wọn, torí ilẹ̀ wọn á di ahoro pátápátá+ torí ìwà ipá gbogbo àwọn tó ń gbé ibẹ̀.+ 20 Àwọn ìlú tí wọ́n ń gbé yóò di ahoro, ilẹ̀ náà yóò sì ṣófo;+ ẹ ó sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.”’”+

21 Jèhófà tún sọ fún mi pé: 22 “Ọmọ èèyàn, òwe wo ni wọ́n ń pa ní Ísírẹ́lì yìí, pé, ‘Ọjọ́ ń lọ, gbogbo ìran ò ṣẹ’?+ 23 Torí náà, sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Mi ò ní jẹ́ kí wọ́n sọ ọ̀rọ̀ yìí mọ́ ní Ísírẹ́lì, wọn ò sì ní pa á lówe mọ́.”’ Àmọ́ sọ fún wọn pé, ‘Ọjọ́ ń sún mọ́lé,+ gbogbo ìran yóò sì ṣẹ.’ 24 Torí kò ní sí ìran èké tàbí ìwoṣẹ́ ẹ̀tàn mọ́ nínú ilé Ísírẹ́lì.+ 25 ‘“Torí èmi Jèhófà, yóò sọ̀rọ̀. Ohun tí mo bá sọ sì máa ṣẹ láìjáfara.+ Ìwọ ọlọ̀tẹ̀ ilé, ní àwọn ọjọ́ rẹ,+ ni èmi yóò sọ ọ̀rọ̀ náà, màá sì mú un ṣẹ,” ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.’”

26 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 27 “Ọmọ èèyàn, ohun tí àwọn èèyàn* Ísírẹ́lì ń sọ nìyí, ‘Ìran tó ń rí ṣì máa pẹ́ kó tó ṣẹ, ó sì ń sọ tẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́ iwájú tó ṣì jìnnà gan-an.’+ 28 Torí náà, sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “‘Kò sí èyí tó máa falẹ̀ nínú gbogbo ọ̀rọ̀ mi; gbogbo ohun tí mo bá sọ ló máa ṣẹ,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.”’”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́